Kòkòrò Olújẹ (Bacteria) àti Kòkòrò Àrùn (Viruses)
Kòkòrò olújẹ àti àrùn ló ń fa àrùn, ṣùgbọ́n òògùn apakòkòrò ń ṣiṣẹ́ fún kòkòrò olújẹ (bacteria) nìkan.
Òkòrò Àìfojúrí Virus
- Tó fimọ́ òtútù, ọ̀rìnrìn, laryngitis, òtútù àyà (bronchitis), àti èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ààrùn inú-ọ̀fun.
- Wọn máa ń ràn ni ju àwọn àìsàn kòkòrò àìfojúrí bacteria lọ. Ti àwọn tó ju ènìyàn kan lọ nínú ẹ̀bí bá ní àìsàn náà, ó ṣeéṣe kí o jẹ àìsàn kòkòrò àìfojúrí Virus.
- O lè jẹ́ kí o ṣàìsàn gẹ́gẹ́ bíi ti àìsàn kòkòrò àìfojúrí bacteria.
O ma̒ n balè la̒ra la̒arı̒n ọjọ̒ mẹ̒rin si ma̒ruun àmọ̒ o̒ le to̒ ọ̀sẹ̀ mẹ̀ta kı̒ ara o̒ to̒ padà sı̒pò.
- Òògùn apakòkòrò kò ṣiṣẹ́ fún àrùn àìfojúrí virus
Àìsàn kòkòrò àìfojúrí Bacteria
- Wọn kò wọ́pọ̀ bíi ti àìsàn kòkòrò àìfojúrí ti virus.
- Kìí tàn kálẹ̀ kíákíá láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan sí ìkejì bíi ti kòkòrò àìsàn ti virus.
- Àwọn àpẹẹrẹ tó wọ́pọ̀ ni kí ọ̀nà-ọ̀fun máa yúnni àti àwọn àìsàn òtútù àyà.
- Àwọn òògùn apakòkòrò (antibiotics) máa n ṣiṣẹ́ fún àìsàn kòkòrò àìfojúrí (bacteria), ṣùgbọ́n kò ṣe pàtàkì ní gbogbo ìgbà

Ìkọjújasí Oògùn apakòkòrò
Ló àwọn ògùn apakòkòrò pẹ̀ lú ọgbọ́n láti ṣàdínkù dídàgbà ìdojújàkọ òògùn apakòkòrò.

Ọwọ́ fífọ
Fífọ ọ̀wọ́ ní ọ̀nà tí ó dára jù láti fòpin sí Àwọn àtànkálẹ̀ àìsàn.
Ibà
Ibà mán mú ara gbónà, ní ìgbàgbogbo nítorí àìlera. Àwọ̀ tó pupa, gbóná, àti èyí tíó gbẹ, kódà lábẹ́ abíyá, jẹ́ àmì ibà.
Bí ara rẹ tàbí ara ọmọ rẹ ṣe gbóná sí dá lórí ibi tí o ti ṣe òdinwọ̀n rẹ̀.
Ibà:
- O ràn ara lọ́wọ́ láti dojú ìjà kọ àìsàn.
- Ó lè ṣẹlẹ̀ kòkòrò Olújẹ (Bacteria) àti kòkòrò Àrùn (Viruses).

Alákóso:
- Ibà jẹ́ ohun àbò tí o ṣèrànwọ́ fún ara láti bá àìsàn jà. Ibà lè wáyé nínú àwọn àìsàn kòkòrò Olújẹ (Bacteria) àti kòkòrò Àrùn (Viruses).
- Ní èrò lílo aceptaminophen tàbí ibuprofen (ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà to ba wá) Tí ara ẹni tó ni iba náà kò bá balẹ̀ .
Wọ aṣọ tí kò wúwo jù sí ara rẹ tàbí fún ọmọ rẹ kí ara rẹ bàálè kí o má bàá máa gbọ̀n, nítori gbígbọ̀n á máa tùbọ̀ ṣe okùnfà oru síi. Jẹ́ kí ìwọ̀n gbígbóná yàrá rẹ wà ní bíi ogún tàbí kí o tutu níwọ̀nba.
Mu ọ̀pọ̀lọpọ omi tútù. Fún ọmọ rẹ ní omi tó tutu mu tàbí àwọn elerin dodo tódi ní gbogbo wákàtí tí o ba jí.
Bí ẹnikẹ́ni ọmọde̒ àbı̒ àgbàlagbà bá ní ibà tí ara re si nsu tí o sì ti lo sı̒ ibi ti àìsàn ìgbónà olódè (Measles) tí ń tanka̒, kàn sí Health Link (tẹ 811 ní Alberta) láti gba àmọ̀ràn lórí ìgbésẹ̀ tó dára jùlọ.
Òtútù àti Ṣíṣàn Ikunmu
Àwọn kòkòrò àrùn (virus) tí ó ṣòkùnfà otútù tó bíi ìgbẹ̀ta òtọ̀tọ̀. Àwọn ọmọdé lè ní mẹjọ sí mẹwàá. òtútù ní ọdún. Àwọn àgbàlagbà ní òtútù tí kòpọ̀ nítorí wọ́n ti ní ààbò ara tó ń dènà àwọn kòkòrò àrùn (virus) náà. Àwọn òògùn apàkórò kò ṣiṣẹ́ lòdì sí otútù tí kòkòrò àrùn fa.
Àwọn Àmì Àìsàn:
- Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ , Ẹ̀fọ́rí, Ibà, yíyọ omi lójú, lẹ̀yin náà imú ṣíṣàn, egbò ní ọ̀nà-ọ̀fun, sísín, àti wíwúkọ́.
- Ikun láti imu máa ń jẹ fúnfún ní ìbẹrẹ, ṣùgbọ́n ó máa ń di pupa tàbí aláwọ̀ ewé.

Ìdènà:
- Fọ ọwọ́ rẹ láti dènà ìtànkálẹ̀ àwọn kòkòrò àrùn (virus) tó ń ṣokùnfà òtútù.
- Kọ àwọn ọmọ rẹ láti máa fọ ọwọ́ wọn.
Ìṣàkóso:
- Mu omi tó pọ̀, ní gbogbo ìgbà.
- Ní èrò lílo aceptaminophen tàbí ibuprofen (ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà to ba wá) Tí ara ẹni tó ni iba náà kò bá balẹ̀.
- Tí o ba nì òtútù tàbí tí o bá ń ṣe ìtójú ẹnití ó ní òtútù, fọ ọwọ́ rẹ nígbàgbogbo láti dènà kíkóoran àwọn ẹlòmíràn.
- Oògùn ikọ̒ àbı̒ oògùn ọ̀fìnkìn le dı̒n aamı̀ òtu̒tù kù ṣùgbọ́n kò ní dín gígùn òtútù náà kù.
Àkíyèsí: Ma̒ se lo àwọn oògùn yii fu̒n ọmọ̒de̒ tı̒ ọjo̒ orı̒ wọn kò to̒ ọdu̒n mẹ̒fà.
Àkíyèsí: àwọn oògùn ọ̀fìnkìn (decongestant) tàbí oògùn ikọ́ lè ní èròjà tı̒ o̒ le dı̒nkù àmı̀ àıs̀àn ibà. Ka àwọn ıwe ̀ ̒ àlẹ̀mọ́ dáradára kí o sì ṣe àyẹ̀ wò pẹ̀lú onímọ̀ òògùn tàbí dókítà rẹ láti yàgò fún àlòjù.
Lo omi-iyọ̀ (saline) tó wà fún ìtọ́jú imù ríro láti ṣe ìtọ́jú imù dáradára, pàápàá jùlọ fún àwọn ọmọ ìkókó àtí àwọn ọmọdé. Lo omi-iyọ̀ tí wọ́n ń ta lọ́ja tabi finfin tabi ki o se tire.
Awọn omi Iyọ àgbéléṣe tó ń kán
Pòó Papọ̀:
- Ife kan (240 mL) omi tí ó gbe kànà tí ó wà tútù (tí o ba ń lo omi ẹ̀rọ, gbée kaná fún iṣẹ ́ jú kan, kó silẹ̀. )
- ½ tsp (2.5 g) iyọ̀
- ½ tsp (2.5 g) baking soda
Da àpòpọ̀ yii sı̒nu̒ ìgò tı̒ o̒ mọ̒ pèlu̒ tàbı̒ ıgò ala̒fọwọ̒tẹ̀ (o wà ní àwọn ilè àtajà ògùn), o̒sı̀ tu̒n le lo ìgò sirinji onídiróbótó. Máa ṣe àpòpọ̀ ògùn tuntun nı̒ ojọ́ mẹta mẹta.
Láti Lò:
- Jókòó kí o rọra gbè orí rẹ sẹ́ yìn díẹ̀. Máṣe dùbúlẹ̀. Fi etí ìgò, sirinji róbótó oníke-nídí, tàbí ìgo àfọwọ́ tẹ̀ si ihò imù kan, Rọra fàá tàbí tẹ díẹ̀ sínú ìhò imú rẹ. Ba̒kanaa fún ìho imú rẹ èkejì. Nu etı̒ ìgò róbótó-oníke-nídí náà pẹ̀ lú aṣọ tó mọ́ lẹyin gbogbo ìgbà tí o bá ti lòó.
Àìsàn ọ̀fìnkìn
Àìsàn ọ̀fìnkìn (tàbí ọ̀fínkìn) ní kòkòrò àrùn (virus) ṣe okùnfà rẹ̀. Àgbàlagbà pẹ̀lú àìsàn ọ̀fìnkìn lè ṣe kòkòrò àrùn (virus) virus náà sí ẹlòmíràn fún ọjọ́ mẹta sí márùn lẹ́yìn tí àmì àìsàn náà bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọmọdé pẹ̀lú àìsàn ọ̀fìnkìn lè ṣe ìtànkálẹ̀ àrùn náà sí ẹlòmíràn títí ọjọ́ mẹje.
Àwọn àmì àìsàn:
- Ibà/òtútù
- Ẹ̀fọ́rí
- Iṣan tàbí ara díduni
- Rírẹni
- Egbò ọ̀nà-ọ̀fun
- Imú ṣíṣàn tàbí imu dídí/sísín
- Ikọ́

Ìdènà:
- Gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kòkòrò àrùn ọ̀fìnkì lọ́dọọdún.
- Fọ ọwọ́ rẹ, pàápàá lẹ́yìn ìgbà tí o ba wà pẹ̀lú aláìsàn. Kọ ọmọ rẹ nipa fífọ ọwọ́.
- Bo imú àti ẹnu rẹ nígbàtí o bá sín tàbi wúkọ́ .
- Kọ́ ọmọ rẹ láti lo ìwà èémí tó dára.
Ìṣàkóso:
- Mu ọpọlọpọ omi.
- Simi dáradára tàbí kí o fàyègba ọmọ rẹ láti simi dáradára. Dúró sílè tàbí kí o fi ọmọ rẹ pamọ́ sínú ilé fún àwọn ọjọ́ díẹ̀ ní ìgbà tí àìsàn náà bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ láti simi àti láti dènà ìtànkálẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn.
- Ní èrò latilọ aceptaminophen tàbí ibuprofen (ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà to ba wá) fún ibà, ẹ̀fọ́rí, àti ara ríro.
Àkókò ọ̀fìnkìn sáábà máa bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù Kọkọ̀nlá tàbí oṣù Ìkejìlá ní ọdọọdún ó sì máa ńparí ní oṣu Kẹ́rin tàbí oṣù Ìkárún. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àìsàn ọ̀fínkìn lè yọrí sí òtútù àyà.
Àkóràn àisàn àyíká imú
Àyíká imú jẹ́ àyíká tí ó kún fún afẹ́fẹ́ tó wà ní àyíká imú àti ojú. Ọ̀fìnkìn máa ń wáyé nígbà tí omi bá kọ́ kún sínú àyíká imú.
Àìsàn àyíká imú máa ń wáyé jùlọ lẹ́yìn otútù, ṣùgbọ́n púpọ̀ ninu otútù kò ní fa àrùn kokoro. Ààmì àìsàn àyíká imú lera ó sì ń pẹ́ ju otútù lọ.
Àkíyèsí: Tí àwọn àmì náà bá wà pẹ̀lú egbò-ọ̀nàfun àti/tàbí ikọ́, wo òtútù àti/tàbí àìsàn ọ̀fìnkìn.

Àwọn àmì àìsàn:
Ìrora ní iwájú ojú tàbí orí fifo, ìrora orí, ìrora eyín, ìrẹ̀wẹ̀sì, ìkọlù, ibà.
Imú tí ó dí pẹ̀lú ṣíṣàn aláwọ̀ òféèfé tàbí aláwọ̀ ewé tí ó pẹ́ ju ọjọ́ 10 lọ jẹ́ àmì pé o lè nílò àwọn òògùn apakòkòrò.
Ìṣàkóso:
- Ní èrò lílo aceptaminophen tàbí ibuprofen (ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà to ba wá) fún ara ríro àti ibà.
- Fun awọn ọmọde, lo kíkán omi-iyọ̀ tabi fín lati ṣe iranlọwọ lati ṣe ìrọ̀rùn ba imu ṣiṣàn (wo òtútù / Imú ṣíṣàn fun ohunelo ni Oju-iwe ọ̀jú ewé kéṣàn); Fun awọn àgbàlagbà, lílo omi iyọ yóò ṣiṣẹ́ tó dájú.
- Òògùn tí ó máa mu otútù àti ìkọ̀lù dídá lè ṣe ìrọ̀rùn bá àìlèmí dáradára ṣùgbọ́n kò nílè dín gígùn àìsàn náà kù.
Àkíyèsí: Máṣe fún àwọn ọmọ ìkókó tàbí àwọn ọmọdé tó wà lábẹ́ ọdún mẹfa ní àwọn ohun èlò wọ̀nyí.
Àkíyèsí: Òògùn tí ó máa mu otútù àti ìkọ̀lù dídá lè ní ibà tí ó ń dín ògùn kù bákannáà. Ṣàkíyèsí àwọn àmì dáadáa kí o sì ṣàyẹ̀wò pẹ̀lú oníṣègùn tàbí dókítà rẹ láti yẹra fún àlòjù ògùn.
Kòkòrò Olújẹ (Bacteria) àti Kòkòrò Àrùn (Virus) lè ṣokùnfà wíwú àyíká imú (àwọn kòkòrò àrùn (vírus) wọ́pọ̀ tó ìgbà).
Egbò ọ̀nàfún
Egbò ní ọ̀nà-ọ̀fun sábà máa ń wà pẹ̀lú Òtútù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egbò-ọ̀fun ni àwọn kòkòrò àrùn máa ń ṣokùnfa. Òògùn apakòkòrò kò lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún egbò ọ̀nà-ọ̀fun tí kòkòrò àrùn fa.
Àwọn egbò ọ̀nà-ọ̀fun kan ní kòkòrò Streptococcus tí kòkòrò olújẹ (bacteria) fà. Tí egbò ọ̀nà-ọ̀fun bá kọ́wọ́ rìn pẹ̀lú imú ṣíṣàn, ikọ́, ojú-pípọ́n, kíkẹ̀, tabi ìgbẹ́-gburu, ó ṣè nṣe kí o jẹ ntorí kòkòrò àrùn (virus) kìí sìí ṣe ọ̀nà ọ̀fun dídùn nikan.

Dókítà rẹ kòlè sọ bóyá egbò ọ̀nà-ọ̀fun ni o ni nipa wíwòó nìkan.
- Tí ọgbẹ́ ọ̀fun náà bá jẹ́ ara òtútù, ó ṣe é ṣe kí kòkòrò àrùn (virus) fàá àti pé a kò kò nílò àyẹ̀wò ọ̀nà ọ̀fun.
- Tí o kò bá ní àmì òtútù, dókítà rẹ lè lo àyẹ̀wò ọ̀nà-ọ̀fun láti fi hàn bóyá kòkòrò olújẹ (bacteria) tàbí kòkòrò àrùn (virus) ní o fàá. Àwọn èsi àyẹ̀wò sábà máa n jade ní àárín wákàti méjídínláàdọ́ta.
- Tí àwọn èsì àyẹ̀wò náà bá fihàn pé o kò ní àrùn, àwọn òògùn apakòkòrò kò ní ṣiṣẹ́ nítorí pé ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ pé kòkòrò àrùn (virus) ní o fa egbò ọ̀nà-ọ̀fun náà.
- Ti àwọn èsì bá ṣàfihàn pe o ní àrùn náà, dókìta rẹ̀ lè pinu láti ṣàpèjúwe ògùn aporó fún ọ.
- Àwọn mọ̀lẹ́bí wakò nílòláti ṣàyẹ̀wò àyàfi tí wọńn bá ṣe àìsàn.
Ìṣàkóso:
- Mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
- Ní èrò lílo aceptaminophen tàbí ibuprofen (ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà to ba wá) fún ọ̀nà-ọ̀fun ríro àti ibà.
- Fún àwọn ọmọ ọjọ́ ori ọ̀dún mẹ́fà àti jùbẹ́ẹ̀ lọ àti àwọn àgbàlagbà, lílo ògùn oníkòrò lè mú àìsàn náà kúrò.
Àkíyèsí: A kò gbọdọ̀ fún àwọn ọmọ kékeré ní ògùn oníkòrò nítorí òlé dì ọ̀nà ọ̀fun. - Fún àwọn ọmọdé tó ti di àgbàlagbà àti àwọn àgbàlagbà, fífọ ẹnu pẹ̀lú omi-iyọ̀ tólọ́ wọ́rọ́wọ́ yóò jẹ́ kí ọ̀fun náà dára. Po idaji simbi iyọ̀ pẹ̀lú ìfé kan (250 ml) omi lílọ́ . Fí fọ ẹnu fún ìṣẹ́ju mẹwa. O lè ṣe ní ìgbà mẹrin sí márùn lójúmọ́ .
- Ìwọ àti ọmọ rẹ le padà sí iṣẹ tí ó yẹ nígbà tí ara rẹ bá yá.
Etí Ríro
Tùbù Eustachian ló so etí àárín àti ẹ̀yìn ọ̀fun pọ̀. Nitori pe ọ̀pá yii jẹ tẹ́ẹ́rẹ́ nínú àwọn ọmọdé kékeré, ó lè dí, pàápàá jùlọ pẹlu òtútù. Dídí náà le fa àìsàn.
Ó ṣe pàtàkì láti ṣe àkíyèsí pé àádọ́rin sí ọgọ́rin ninu ọgọ́rùn àwọn ọmọdé tí ó ní àìsàn etí yóò ní ìwòsàn láì òògùn apakòkòrò. Àwọn aìsàn etí kan jẹ́ nítorí kòkòrò àrùn (virus) àwọn kan jẹ́ nítorí kòkòrò olújẹ (bacteria). Kíkíyèsára nìdúró jẹ́ ọ̀nà tí ó tọ́ tí dókítà rẹ lè dábàá.

Àwọn àmì àìsàn:
- Ibà
- Èti ríro
- Ìbínú
Idènà:
- Fọ ọwọ́ rẹ déédé kí o sì kọ ọmọ rẹ ní ọwọ́ fífọ̀ níwọn tí ọ̀pọ àìsàn etí máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn òtútù.
- Jẹ́ kí ọmọ rẹ yàgò fún èéfín gbogbo.
- Máṣe fún ọmọ rẹ ní ìgò láti mu nígbàtí o ba wà ní ìdùbúlẹ̀ .

Ìṣàkóso:
- Ní èrò lílo aceptaminophen tàbí ibuprofen (ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà to ba wá) fún ríro àti ibà.
- Gbe aṣọ tó lọ́ wọ́rọ́wọ́ lé òde eti rẹ.
- Antihistamines ati decongestants kò lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àìsàn eti.
- Lábẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan dókítà rẹ lè kọ àwọn òògùn apakòkòrò lẹ́yìn àyẹ̀wò etí ọmọ rẹ.
- Nítorí ewu ìdènà àwọn ìdojújàkọ ògùn, a kò dábàá rẹ̀ mọ́ láti fún àwọn ògùn apakòkòrò fún ìgbà pípẹ́ láti dènà àìsàn etí.
Ikọ́
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikọ́ lára àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọmọdé ni ó ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ àìsàn kòkòrò àrùn (virus) ìpa ọ̀nà èémí (wo àtẹ ìsàlẹ̀). A gbọ́dọ̀ lo àwọn ògùn apakòkòrò fún ikọ́ nìkan tí aláìsàn náà bá ní àrùn ẹ̀dọ̀fóró nítorí kòkòrò olújẹ (bacteria), àrùn tàbí àyẹ̀wò fìdí rẹ múlẹ̀ fún pertussis (ikọ́ líle).
Àwọn àmì àìsàn:
- Ibà, ikọ́, àti àyà dídùn.
- Wíwúkọ́ ikun tí ó lè jẹ́ àwọ̀ òféèfé tàbí aláwọ̀ ewé. Èyi kò túmọ̀ sí í pé o jẹ́ àìsàn bacteria.
- Ìṣòro mímí lè ṣẹlẹ̀.
ÀKÍYÈSÍ: Pẹ̀lú àrùn bronchitis, ogójì ninu ọgọ́rùn àwọn ènìyàn ṣì ń wúkọ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì. Ẹ́ẹdọ́gbọ̀n ninu ọgọ́rùn àwọn ènìyàn ṣì ń wúkọ́ lẹ́yìn ọ̀ sẹ̀ mẹ̀ta.

Ṣíṣàìsàn | Ìkànnì | Ẹgbẹ́ ọjọ́ orí | Okùnfà |
Laryngitis | Àwọn okùn ohùn | Àwọn ọmọdé tó ti dàgbà/ àwọn àgbàlagbà | Kòkòrò Àrùn Virus |
Àwọn ọmọdé ti ọ̀nà ọ̀fun wọn wú | Àwọn okùn ohùn àti ọ̀pá-afẹ́fẹ | Àwọn èwe | Kòkòrò Àrùn Virus |
Bronchitis1 | Ọ̀pá èémí (ńlá) | Àwọn ọmọdé tó ti dàgbà/ àwọn àgbàlagbà | Kòkòrò Àrùn Virus |
Bronchiolitis | Opa èémí (kékeré) | Àwọn ọmọ ìkókó | Kòkòrò Àrùn Virus |
Àìsàn òtútù àyà | Awọn apo afẹfẹ | Gbogbo ọjọ́ orí | Bacteria tàbí virus |
Ikọ́ líle | Imú sí ẹ̀dọ̀ -fóró | Èyíkeyí ọjọ́ orí | Bacteria |

1Àwọn aláìsàn tí wọ́n ní àrùn ẹ̀dọ̀fóró ọlọjọ́ pípẹ́ máa ní àìsàn kòkòrò àìfojúriu bacteria nígbà tí wọ́n bá ní àìsàn bronchitis.
Ìṣàkóso:
- Mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
- Ògùn tí ó ń tẹ̀rí ikọ̀ ba le ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọdé tó ti dàgbà àti àwọn àgbàlagbà.
ÀKÍYÈSÍ: Máṣe fún àwọn ọmọ ìkókó àti àwọn ọmọdé ní abẹ́ ọdún mẹ́fà ní ohun èlò wọ̀nyí.
ÀKÌYÈSÍ: Ògùn ikọ̀ náà lè ní eroja ìbà tí ó ń dín ògùn kù. Ka àwọn àmì dáadáa kí o sì ṣàyẹ̀wò pẹ̀lú oníṣègùn tàbí dókítà rẹ láti yẹra fún àlòjù ògùn. - Àwọn ògùn ikọ́ tàbí ògun oníkóró lè ran àwọn ọmọdé àgbàlagbà àti àgbàlagbà lọ́wọ́ . Yàgò fún ògùn ikọ́, kòkòrò olújẹ (bacteria) nítorí wọ́n lè yọrí sí ìdènà àwọn ògùn.
ÀKÌYÈSÍ: A kò gbọ́dọ̀ fún àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò tó ọdún mẹ́fà ní ògùn ikọ́ nítorí ewu àìfọ̀kànbalẹ̀ . - Wọ́n dábàá x-ray àyà láti ṣe àyẹ̀wò àìsàn ẹ̀dọ̀fóró ti kòkòrò olújẹ (bacteria). Ní kété tí wọ́n bá ti ṣe àyẹ̀wò àyẹ̀wò náà, wọ́n máa ń fún àwọn ògùn apakòkòrò ní àṣẹ.
Àwọn Àmì àìsàn tó Lágbára Kí ó yẹ kí Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Oníṣègùn rí
Àwọn àmì wọ̀nyí nílò àkíyèsí dókítà tàbí oníṣègùn nọ́ọ̀sì.
Ibà:
- Tí ọmọdé lábẹ́ oṣú mẹ̀ta bání ibà, a gbọ́dọ̀ rí wọn ní ojú ẹsẹ̀ .
- Ti ọmọdé èyíkéyí ọjọ́ orí bá ní ibà tí ó sì dàbí ẹni pé kò ní ìlera, wọn yẹ ní rírí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ .
- Ti ọmọdé èyíkéyí ọjọ́ orí bání ibà fún ìgbà tó ju ọjọ́ mẹ̀ta, wọn yẹ ní rírí láàrín wákàtí mẹrinlelogun.

Etí Ríro
Ri dókítà tí ọmọdé náà bá ní etíríro àti:
- Bákannáà ní wọ́n ní ibà tó ga; tàbí
- Ó dàbí ẹnipé ara wọn kòyá; tàbí
- Wọ́n ní pupa tàbí wíwú lẹ́hìn etí; tàbí
- Ìrora etí wọn le ju fún wákàtí mẹrinlelogun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́ n lo acetaminophen / ibuprofen.

Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ní ibà tàbí àwọn àìsàn mìíràn gbọ́dọ̀ máa gbèrò láti kàn sí dókítà wọn tàbí nọ́ọ̀sì oníṣègùn wọn tí àwọn àmì àìsàn náà bá burú sí i tàbí tí wọ́n le gan-an.
Ní Alberta, o lè pe Health Link (ní 811) tí o bá nílò àmọ̀ràn tàbí ìgbésẹ̀ tó dàra jùlọ láti gbé kò yé ọ.
Fún àwọn àmọ̀ràn tó ṣeé ṣiṣẹ́ lé lórí lóri àwọn ìṣòro ìlera àwọn ọmọdé, ṣàbẹ̀wò si a ahs.ca/heal, Ohun èlò ìròyìn gbogbogbò tí Stollery Children’s Hospital ń tọ́jú.
Àwọn Àmì Ìlera Pàjáwìrì
Tí ìwọ tàbí ẹni tí ò ń tọ́jú fi èyíkéyìí nínú àwọn àmì wọ̀nyí hàn, jọ̀wọ́ wá ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ibà
Wá ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí:
Ẹni tí ọjọ́ orí èyíkéyìí tí ó ní ibà máa ń bínú gan-an tàbí sísúni (ó ṣòro láti jí tàbí kí ó wà ní ìdìde), ó ń bì léraléra, ó sì lè ní ọrùn líle tàbí ara sisun ńlá tí kò lọ nígbà tí o bá tẹ àwọn ààyè náà (tí ó lè dàbí àwọn òjú ègbo kékeré).

Mímí
Wá ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí:
- Ẹni tí ó ń ṣàìsàn ti ọjọ́ orí èyíkéyìí ní ìṣòro mímí (tí kìí ṣe imú dídí nío fàá).
- Ẹni tí ó ń ṣàìsàn, mí kíákíá tàbí lọ́ra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tàbí ó ní ètè aláwọ̀ búlúù, ọwọ́ , tàbí ẹsẹ̀ .

Ipò Gbogbogbò
Wá ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí:
- Ẹni tí ó ń ṣàìsàn ti èyíkéyí ọjọ́ orí ṣòro láti jí tàbí láti mú kówà ní àìsùn tàbí ó rújú púpọ̀ , ìbínú, tàbí ìdààmú ju ti bóṣeyẹ lọ, ó ní ìrora orí tó lágbára tí kò ní lọ, ó ní ọrùn líle, ó ti gbẹ́ tàbí awọ ara tí ó pọ́n gan-an tàbí ó dàbí ẹni pé ó tutù sí ìfọwọ́kàn.
- Ẹni tí ó ń ṣàìsàn ní àmì àìsàn omi ara gbígbẹ tí ó ní awọ gbígbẹ, ẹnu gbígbẹ, ààyè ìrọ̀rùn tí ó ti rì (fontanelle) nínú ọmọ, tàbí ó ń tọ ìtọ̀ kékeré.

Àwọn ìdí míràn láti wa ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wà lára:
Ti aláìsàn bá ní ìṣòrò láti gbé ǹkan mi tàbí ó ń datọ́ lẹ́nu.
Tí aláìsàn tí èyíkéyí ọjọ́ orítí bá rọ̀, kò lè rìn, tàbí ó gan.
Àlàyé yìí ni a fún ni bíi ìtọ́kasí nìkan. Ní gbogbo ìgbà, o gbọ́dọ̀ lo ìmọ̀ àti ìdájọ́ tìrẹ nípa bóyá o nílò láti bá dókítà, nọ́ọ̀sì, tàbí oníṣègùn nọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀ .
Ní Alberta, o lè pe Health Link (ní 811) tí o bá nílò àmọ̀ràn tàbí ìgbésẹ̀ tó dàra jùlọ láti gbé kò yé ọ.
Ìkọjújasí Oògùn apakòkòrò
Kínni ìdojújàkọ oògùn apakòkòrò?
- Èyíkéyí lílò àwọn oògùn apakòkòrò, yálà fún àwọn ìdí tí ó tọ́ tàbí èyítí kò tọ́, lè já sí ìdojújàkọ oògùn apakòkòrò. Láti ṣàdínkù ìdàgbàsokè ìdojújakọ oògùn apakòkòrò, a gbọ́dọ̀ lo àwọn oògùn yìí nígbà tí a bá nílò rẹ̀.
- Ìdènà àwọn oògùn apakòkòrò jẹ́ ìlànà ìdáàbòbò àwọn kòkòrò àrùn tí ó ń jẹ́ kí wọ́n yè kí wọ́n sì pọ̀ sí i, kódà nígbà tí oògùn apakòkòrò bá wà. Kòkòrò olújẹ tí ó ní ìdojújàkọ oògùn apakòkòrò ní a sábà máan pè ní “superbugs”.
- Nígbàtí kòkòrò olújẹ bá ní ìdójújàkọ sí òògùn apakòkòrò, òògùn apakòkòrò tí ó ti ṣiṣẹ́ nígbà kan rí kò ní ṣiṣẹ́ mọ́.
- Àrùn tí kòkòrò olújẹ tó ní ìdójújàkọ sí òògùn apakòkòrò ń fa, ṣòro láti tọju, àti nígbà míràn, kò ṣeé ṣe pátápátá. Èyí lè fa àìsàn tó gùn jù lọ tàbí ikú.
- Ràntí, kòkòrò olújẹ (bacteria) ní ìfàyàrán (Ìdojújàkọ)—KÌǏ ṢE ÎWỌ! Gbogbo àwọn ènìyàn tó ní ìlera pípé tí kò ì tíì lo àwọn oògùn apakòkòrò ri ní o lè kó àrùn ìdojújàkọ oògùn apakòkòrò tí kòkòrò olújẹ láti orísun míràn.
Àwọn òògùn apakòkòrò kò ní ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn àìsàn tí àrùn (virus) ń fa, bíi òtútù, ibà-ọ̀rìnrìn, àti bronchitis (òtútù àyà). Lílo àwọn òògùn apakòkòrò fún àwọn àìsàn wọ̀nyí lè yọrí sí ìdójújàkọ sí òògùn apakòkòrò.
Kínni ó yẹkí o ṣe?
- Máṣe retí láti gba òògùn apakòkòrò nígbàtí ìwọ tàbí ọmọ rẹ ní òtútù tàbi wúkọ́. Ọ̀pọ̀plọpọ̀ àwọn àìsàn wọ̀nyí ní kòkòrò máan fa òògùn apakòkòrò kò sì le ṣèranwọ́ .
- Kan si dókítà rẹ láti mọ́ bóyá kòkòrò olújẹ (bacteria) tàbí àrùn (virus) ló fa àìsàn rẹ, àti bóyá òògùn apakòkòrò ní o nílò.
- Ṣe sùúrù nígbàtí ìwọ tàbí ọmọ rẹ bá ní àwọn àmì àìsàn òtútù, ikò, tàbí egbò ní ọ̀nà-ọ̀fun. Àwọn tó pọ̀jù nínú àwọn àìsàn tí àrùn (virus) ń fa máa ń gba ọjọ́ mẹ́rin sí márùn-ún kí ara bẹ̀rẹ̀ sí ní dáradára, yóò sì tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí ìwòsàn pátápátá lè ṣẹlẹ̀.
- Ní àkókò òtútù tàbí ní ìgbà ibà ọ̀rìnrìn, fọ ọwọ́ rẹ déédé láti yàgò fún ṣíṣe àìsàn. Tẹ̀lé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àmọ̀ràn wa lóri ọwọ́ fífọ̀ ní ojú ewé tí o kàn.
Yàgò fún ìjà pẹ̀lú KÒKÒRÒ TÓ NÍ ÌDÓJÚJÀKỌ GÍGÀ. Lò òògùn apakòkòrò pẹ̀lú ọgbọ́n!
Ọwọ́ fífọ
Ọwọ́ fífọ̀ ní ọ̀nà tó dára jùlọ láti dẹ́kun títànkálẹ̀ àwọn àrùn.
Ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àrùn tó wọ́pọ̀ lè tan káàkiri nípasẹ̀ ọwọ́.
Ìgbà tí o yẹ láti fọ àwọn ọwọ́:
- Ṣáájú oúnjẹ
- Ṣáájú, ní àkókò, àti lẹ̀yín ìgbà ti a bá ń wá oúnjẹ
- Ṣáájú fífún ọmọ ní ọmú
- Lẹ́yìn ìgbà tí o bá lo ìlé ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí tí o bá ń ran ọmọdé lọ́wọ́ láti lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀
- Ṣáájù àti lẹ́yìn ìgbà tí o bá pààrọ̀ àwọn aṣọ ìdí ọmọ tàbí àwọn ohun èlò ìmọ́tótó obìnrin
- Lẹ́yìn ìgbà tí o bá fọn imú tàbí nu imú ọmọ
- Lẹ̀yín ìgbà tí o bá di àwọn ǹkan tí o pín pẹ̀lú àwọn ẹlò míràn mú
- Ṣáájú kíkì àti yiyọ àwọn ìgò ìwòran ojú
- Ṣáájú tàbí lẹ́yìn ṣíṣetọ́jú aláìsàn
- Lẹ́yìn tí o bá fi ọwọ́ kan ẹranko, tàbí fún wọn ní oúnjẹ, tàbí tí o bá ń mú ìdọ̀tí ẹranko (bíi oúnjẹ tó kú tàbí ìgbẹ́ ẹranko) kúrò.
- Ṣáájú àti lẹ́yìn ìgbà tí ba ta ẹyín rẹ

Bí o ṣe lè fọ ọwọ́:
- Lo ọṣẹ àti omi. Fí fi omi lásán nìkan fọ ọwọ́ kò lé àwọn kòkòrò lọ.
- Rẹ àwọn ọwọ́ rẹ.
- Lo ọṣẹ. Máṣe lo ọṣẹ tí o lòdì si kòkòrò àìfojúrí bacteria.
- Fi ọwọ́ rẹ ra ara wọn papọ̀ fún ókéré tán ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí ogún. Fi gbogbo ọwọ́ rẹ gbo ara wọn tó fi mọ àwọn àtẹ́lẹwọ́ rẹ, lárin àwọn ìkawọ́, àwọn àtàmpàkò, ẹ̀yìn ọwọ́ , ọrùn ọwọ́ , orí-ìkawọ́, àti àwọn èékáná.
- Ṣan ọwọ́ rẹ fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá.
- Nú ọwọ́ rẹ pẹ̀lú aṣọ tó mọ́.
Ohun tó yẹ kí o ṣe:
- Reti àwọn dokítà, enitó ń tọ́jú ẹyín, àwọn oníṣègùn láti fọ ọwọ́ wọn kí wọ́n to ṣe àyẹ̀wò fún ọ tàbí ọmọ rẹ.
- Ṣe ìdánilójú pé ọṣẹ tí kò ní oorun wà ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ní ilé ìwé ọmọ rẹ àti níbi iṣẹ́ rẹ.
- Ríi dájú pe ibi tí o ti ń tọjú ọmọ rẹ ni àwọn àyè fún àgbàlagbà àti àwọn ọmọdé láti fọ ọwọ́ wọn.
- Lo ọṣẹ tó mọ́ tí kò ní oorun. Ọṣẹ tí kò ní oorun máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa bíi ọṣẹ tó ń tako kòkòrò olújẹ (bacteria). Ọṣẹ tó ń tako kòkòrò olújẹ kò dára láti lò nítorí pé ó máa ń yọrí sí ìdójújàkọ kòkòrò olújẹ, kò sì ṣiṣẹ́ ju ọṣẹ tí kò ní oorun lọ.
- Kọ́ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ.
Ǹjẹ́ ìdun nílò Àwọn ògùn,
Ìṣàkóso Àwọn àìsàn tó ń ran ni,
Alberta Health Services.
DBND@ahs.ca
www.dobugsneeddrugs.org
© 2024 Alberta Health Services,
Ìlera Olùgbé, Ará ilú àti Agbègbè

Iṣẹ́ yìí wà lábẹ́ àṣẹ Creative Commons Attribution-Noncommercial-Share Alike 4.0 International license. Láti wo ẹ̀dá ìwé àṣẹ́ yi, wo https://creativecommons.org/licenses/by-nc-sa/4.0/. O lè ṣe ẹ̀dà rẹ, pin kí o sì faradaiṣẹ́ tí kì í ṣe fún ètò ọrọ̀-ajé, níwọ̀n ìgbà tí o bá ti ṣe àwòmọ́ iṣẹ náà sí Alberta Health Services tí o sì dúró lábẹ́ ìwé àṣẹ míràn. Ti o ba dàárú, ṣàyípadà, tàbí kọ́ lórí iṣẹ́ yi, o lè pín àbájáde iṣẹ́ yi nìkan lábẹ́ ìwé-àṣẹ kannáà, iru, tabi tó baramu. Ìwé-àṣẹ náà kò wà fún àwọn àmì òwò AHS, àwọn àmì tàbí àkóónú tí Alberta Health Services ní àṣẹ-ẹ̀dà fún.
Gbólóhùn Kíkọ̀ láti gbà:
Ohun èlò yí ni a pinnu fún àlàyé gbogboògbò nìkan àti pé a pèsè lori ìpìlẹ̀ “bí ó ti wà”, “ibi tí ó wà”. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbìyànjú tó mọ́gbọ́n dání ni a ṣe láti jẹ́rìí sí ṣíṣe déédé àlàyé náà, Alberta Health Services kò ṣe aṣojú tàbí àtìlẹ́yìn kankan, ṣàfihàn, ìtumọ̀ tàbí òfin, nípa ṣíṣe déédé, ìgbẹ́kẹ̀lé, pípé, lílò tàbí dídúró déédé fún ìdí kan ní pàtó irú àlàyé bẹ́ẹ̀. Ohun èlò yìí kì í ṣe arọ́pò fún ìmọ̀ràn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ òṣìṣẹ́ ìlera tó kúnjú ìwọ̀n. Alberta Health Services ṣẹ́ gbogbo ẹ̀bi fún lílo àwọn ohun èlò wọ̀nyí, àti fún èyíkéyìí ẹ̀tọ́, ìgbésẹ̀ , ìbéèrè tàbí ìpẹ̀jọ́ tí ó wáyé látàrì irú ìlò bẹ́ẹ̀.